Romans 6:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́.