Romans 6:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ti gbé ògbólógbòó ara yín tí ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ sin pẹ̀lú Kírísítì nígbà tí òun kú, àti nígbà tí Ọlọ́run Baba pẹ̀lú agbára ògo mú un padà sí ìyè, a sì fún yín ní ìyè tun tun rẹ̀ láti gbádùn rẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ nípa ìrìbọmi yín.