Romans 7:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ohun ti o dara ha di ikú fun mi bi? Ki a má ri. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ ki o le farahan bi ẹ̀ṣẹ o nti ipa ohun ti o dara ṣiṣẹ́ ikú ninu mi, ki ẹ̀ṣẹ le ti ipa ofin di buburu rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.