Romans 7:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyé, panṣagà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóòsì jẹ́ panṣagà, kódà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.