Romans 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmìíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run