Romans 8:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín.