Romans 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀. Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀.