Romans 8:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ ninu àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gbadura fún. Ṣugbọn Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́dọ̀ Ọlọrun lọ́nà tí a kò lè fi ẹnu sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa.