Romans 8:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ìsòro bá tilẹ̀ ga ju àwọ̀ sánmọ̀ lọ tàbí ní ìsàlẹ̀ omi, ohunkóhun kì yóò lágbára láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí Jésù Kírísítì Olúwa fi hàn nígbà tí ó kú fún wa.