Romans 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ara titun yín ni yóò máa se àkóso yín bí ẹ bá ń rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń gbé inú yín (Ẹ rántí pé, bí ẹnìkan kò bá ní ẹ̀mí Kírísítì tí ń gbé inú rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í se ọmọ-ẹ̀yìn Kirísítì rárá.)