Romans 9:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé, “Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’ N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hóséà pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”