Romans 9:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti bí Ìsáià ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sódómù, a bá sì ti sọ wá dàbí Gòmórà.”