Romans 9:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Baba yín ni àwọn onígbàgbọ́ jàǹkànjàǹkàn àtijọ́ jẹ́. Ọ̀kan nínú yín ni Kírísítì fúnrara rẹ̀ jẹ́. Júù ni òun nínú ara, òun sì ni olùdarí ohun gbogbo. Ìyìn ló yẹ kí ẹ máa fifún Ọlọ́run láéláé.