Ruth 1:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn,