Ruth 1:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimélékì, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Náómì, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Málónì àti Kílíónì àwọn ará Éfúrétà, ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọ́n ń gbé níbẹ̀.