Ruth 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan. Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.