Ruth 2:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rutu obinrin Moabu na si wipe, O wi fun mi pẹlu pe, Ki iwọ ki o faramọ́ awọn ọdọmọkunrin mi, titi nwọn o fi pari gbogbo ikore mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rúùtù, ará Móábù sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣa ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”