Ruth 2:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Naomi si wi fun Rutu aya-ọmọ rẹ̀ pe, O dara, ọmọbinrin mi, ki iwọ ki o ma bá awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe bá ọ pade li oko miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Náómì sì sọ fún Rúùtù, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”