Ruth 2:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí OLÚWA wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn padà pé, “Kí OLÚWA bùkún fún ọ.”