Ruth 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣa ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsìn yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”