Ruth 2:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”