Ruth 4:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu Rutu ara Moabu, aya Maloni ni mo rà li aya mi, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀, ki orukọ okú ki o má ba run ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati li ẹnu-bode ilu rẹ̀: ẹnyin li ẹlẹri li oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àfikún, mo ra Rúùtù ará Móábù opó Málíónì padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrin àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”