Ruth 4:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Òun sì ni baba Jésè tí í ṣe baba Dáfídì.