Ruth 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣe wọn nigbãni ni Israeli niti ìrasilẹ, ati niti iparọ si li eyi, lati fi idí ohun gbogbo mulẹ, ẹnikini a bọ́ bàta rẹ̀, a si fi i fun ẹnikeji rẹ̀: ẹrí li eyi ni Israeli,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ayé ìgbà a nì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàsípàrọ̀ ohun-ìní, fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnikejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Ísírẹ́lì fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.