Song of Solomon 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú Nítorí òòrùn mú mi dúdú Ọmọkùnrin ìyá mi bínú sími Ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà. Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú