Song of Solomon 1:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán. Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣán Ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.