Song of Solomon 3:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi