Song of Solomon 5:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn. Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. Ṣílẹ̀kùn fún mi, arabinrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye, nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù, gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”