Song of Solomon 8:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin, kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà. Bí mo bá pàdé rẹ níta, tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu, kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IWỌ iba jẹ dabi arakunrin fun mi, ti o mu ọmú iya mi! emi iba ri ọ lode emi iba fi ẹnu kò ọ lẹnu; lõtọ, nwọn kì ba fi mi ṣe ẹlẹya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi sí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà.