Song of Solomon 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ní ọgbà àjàrà kan, ní Baali Hamoni. Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a, ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá, fún èso ọgbà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónì ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún fàdákà.