Song of Solomon 8:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́, ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì. Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́, ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta.