Titus 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbọdọ̀ pawọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípaṣẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wón ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ere àìsòdodo.