Titus 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé, “òpùrọ́ ní àwọn ará Kírétè, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, oníwọ̀ra”.