Titus 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn. Wọ́n díbàjẹ́, aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo.