Titus 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ gẹgẹ ni ki awọn agba obinrin jẹ ẹni-ọ̀wọ ni iwa, ki nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikoṣe olukọni ni ohun rere;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí àátí gbé ìgbé-ayé ẹni-ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ wáìnì mímú, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ ohun rere.