Titus 2:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúse wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínú rere, kí wón sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa baà sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.