Titus 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbà wá là. Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀. Ó gbà wá là, nípaṣẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́,