Titus 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí. Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí. Mo sì fẹ́ kí ó ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀, kí àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Olúwa le kíyèsí láti máa fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ rere. Nǹkan wọ̀nyìí dára, wọ́n sì jẹ èrè fún gbogbo ènìyàn.