Titus 3:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán.