Zechariah 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n si dá ańgẹ́lì OLÚWA tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”