Zechariah 1:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ańgẹ́lì OLÚWA náà dáhùn ó sì wí pé, “OLÚWA àwọn ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jérúsálẹ́mù, àti fún àwọn ìlú ńlá Júdà, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”