Zechariah 1:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si binu pupọ̀pupọ̀ si awọn orilẹ-ède ti o gbe jẹ: nitoripe emi ti binu diẹ, nwọn si ti kún buburu na lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’