Zechariah 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?” Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wipe, kini awọn wọnyi wá ṣe? O si sọ wipe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikẹni kò fi gbe ori rẹ̀ soke? ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹruba wọn, lati le iwo awọn orilẹ-ède jade, ti nwọn gbe iwo wọn sori ilẹ Juda lati tu u ka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?” O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Júdà ká, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sòkè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orilẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sorí ilẹ̀ Júdà láti tú enìyàn rẹ̀ ká.”