Zechariah 1:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsìnyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni OLÚWA wí.