Zechariah 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ bère òjo nigba arọ̀kuro li ọwọ Oluwa; Oluwa yio kọ mànamána, yio si fi ọ̀pọ òjò fun wọn, fun olukulukù koriko ni pápa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ OLÚWA; OLÚWA tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlúkù koríko ní pápá.