Zechariah 10:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn oriṣa ti nsọ̀rọ asan, awọn alafọṣẹ si ti ri eké, nwọn si ti rọ́ alá eké; nwọn ntù ni ni inu lasan, nitorina nwọn ba ti wọn lọ bi ọwọ́ ẹran, a ṣẹ wọn niṣẹ, nitori darandaran kò si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán, àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké, wọn sì tí rọ àlá èké; wọ́n ń tu ni nínú láṣán, nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn, a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí.