Zechariah 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibinu mi ru si awọn darandaran, mo si jẹ awọn ewurẹ ni iyà; nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bẹ̀ agbo rẹ̀ ile Juda wò, o si fi wọn ṣe bi ẹṣin rẹ̀ daradara li ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran, èmi o sì jẹ àwọn olórí níyà nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀, ilé Júdà wò, yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.