Zechariah 10:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni igi-èèkàn àgọ́ tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.