Zechariah 10:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí OLÚWA wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.”