Zechariah 10:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè, wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè: ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà.